Àjọ to n ṣe ìwádìí nipa ààbò ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà NSIB sọ wí pé àwọn yóò Jabo ìròyìn nipa ìjàmbá to wáyé ni Ikeja ìlú Eko láàrin ọkọ̀ ojú ìrin ati ọkọ̀ òpópónà to ṣelẹ ninu osù yìí.
Àjọ yìí gba láti ní ìbáṣepọ̀ tó dàn mórán láàrín àjọ pajawiri fún ìjàmbá àti àjọ tó mójú tó ọkọ̀ ojú ìrin àti jo jíròrò bí ètò ààbò yóò tún ṣe nipọn sí ni ìlú Èkó.
Ọ̀gá àgbà fún NSIB, Akin Olateru ló sọ èyí dí mímọ̀ nibi ìbẹ̀wọ̀ sí àjọ méjéèjì.
Ó ní ìwádìí lórí ìjàmbá to wáyé lọ́jọ́ láàrin ọkọ̀ ojú ìrin àti ọkọ̀ òpópónà ni ọjọ́ kọkàndínlọ́gún oṣù kẹta ọdún 2023.
Àjọ NSIB, LASEMA àti NRC ti gbà latí gbé ìgbìmọ̀ ti yóò ṣe ìwádìí tí yóò mú irẹpọ àti ìtèsíwájú bá àwọn Àjọ náà.