Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti sọ dì mimọ pé àṣeyọrí ti òun ṣe nínú ìbò gómìnà to kọjá jẹ ìpè láti ṣe iṣẹ rere síwájú síi fún ipinlẹ Ọ̀yọ́ àti àwọn èèyàn rẹ.
Makinde ló sísọ lójú ọrọ yìí lásìkò tí Alága Ibùdó Igbafẹ Ilaji tó tún jẹ́ Ọtun Apesinọla Ilẹ Ìbàdàn, Onímọ̀ Ẹrọ Dọtun Sanusi ṣe ètò Awẹjẹ-wẹmu láti dawọ ìdùnnú latari bi Gómìnà ṣe jáwé olubori nínú ètò ìdìbò tó kọjá.
Gómìnà, ẹni tó fi ẹmi im’oore hàn sí Olóyè Sanusi fún àtìlẹ́yìn rẹ àti ètò Awẹjẹ-wẹmu to ṣe àgbékalẹ̀ rẹ tẹnu mọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ìṣèjọba òun yóò tẹ síwájú láti máa mú àwọn èèyàn Ìpínlè Ọ̀yọ́ kúrò nínú òṣì bọ sí inú ọrọ̀.
Makinde nínú ọrọ rẹ̀ sọ wí pé “Mo fẹ dupẹ lọwọ Onimọ ẹrọ Dọtun Sanusi, tí o ṣe akojọpọ ètò yìí. Awẹjẹ-wẹmu fún ijawe olubori ní èyí jẹ.
Mo rí dájú wí pé púpọ̀ nínú wà ní ìpolongo ìbò sì wà lára rẹ ṣugbọn gbogbo eyi tí wá sí òpin báyìí, a kò tún gbọdọ̀ máa bú ara wa mọ. Nisinsinyi, àsìkò ti tó láti kọjú sí iṣẹ tó wà níwájú, eléyìí tíì ṣe titẹ síwájú nínú iṣẹ rere ní ṣíṣe láti mú àwọn èèyàn wa Kúrò nínú òṣì lọ sínú ọrọ̀”
Bákan náà, Gómìnà fi àsìkò náà dupẹ lọwọ gbogbo Orí Adé ati Ọrùn Ilẹkẹ, àwọn l’ẹgbẹ-l’ẹgbẹ ati oníṣe ọwọ tó péjú sí ìbi eto Awẹjẹ-wẹmu náà, nígbà tí o ṣàlàyé pé, àṣeyọrí oun nínú ìdìbò to kọjá kò sẹyin wọn. O sì tún dupẹ gidigidi lọwọ àwọn èèyàn Ìjọba Ibilẹ Ona-Ara.
Ṣáájú ninu ọrọ tirẹ, Alága Ibùdó Igbafẹ Ilaji, Olóyè Sanusi so wí pé òun kò fi ìgbà kan ṣe iyè méjì nípa ijawe olubori Gómìnà nínú ìdìbò to kọjá nítorí pé o ti ṣe ohun tó yẹ kó ṣe fún àwọn èèyàn Ìpínlè Ọ̀yọ́.
Olóyè Sanusi wa fi àsìkò náà dupẹ lọwọ gbogbo awọn tó ṣe atilẹyin fún Gómìnà tó fi jáwé olubori. Bákan náà ló tún dupe l’ọwọ àwọn Mogaji agbo ilé, àwọn olóyè, àwọn ọlọja l’ọkunrin àti l’obinrin, àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ láì yọ àwọn olórí ẹlẹsin silẹ.
Abiola Olowe
Ìbàdàn