Take a fresh look at your lifestyle.

Russia Yọ̀ǹda gbèsè ogún Bílíọ́nù Dọ́là fún àwọn orílẹ̀ -èdè Adúláwọ̀

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 226

Putin sọ èyí ní ọjọ́ Ajé, níbi ìpàdé ìjókóo ìgbìmọ̀ aláṣẹ káríayé kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́,Russia-Adúláwọ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí lágbàáyé.”

Russia pa gbèsè tí ó ju ogún Bílíọ́nù Dọ́là lọ rẹ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè Adúláwọ̀,” ó sọ báyìí.

Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí ààrẹ orílẹ̀-èdè Russia ń sọ ọ̀rọ̀ yìí.

Wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ Àpapọ̀ àwọn ètò fún lílo owó yíyá fún ìdàgbàsókè iṣẹ́ àkànṣe ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè Adúláwọ̀, Putin fikún un.

Ó sọ pé wọ́n ti pinnu ọ̀pọ̀lọpọ̀ ètò láàrin ìwọ̀nba àsìkò iṣẹ́ ìgbìmọ̀ náà,àti pé wọ́n yóò ṣàfihàn abala ìmọ̀ àti èròńgbà ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Russia àti Adúláwọ̀ fún àwọn olùkópa.

Fún ìdí èyí, àwọn adari ilé-iṣẹ́ Russia pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ ìdàgbàsókè ọrọ̀-ajé “ti ṣe àgbékalẹ̀ ìkúnjú òṣùnwọ̀n Russia tí yóò sí ọ̀nà tuntun fún àjọṣepọ̀ ọrọ̀ ajé,” Putin tún sọ báyìí.

Leave A Reply

Your email address will not be published.