Take a fresh look at your lifestyle.

Ètò Ìdìbò 2023: Olùdarí Ilé Aṣòfin Èkó dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olùgbé ní Ìpínlẹ̀ Èkó

- Ó ṣe ìlérí láti ṣe iṣẹ́ akíkanjú ní Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin náà

0 217

Olùdarí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó, Aṣòfin Mudashiru Ọbasá ti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òǹdìbò ní Ìpínlẹ̀ Èkó fún bí wọ́n ṣe kópa ní yanturu nínú ètò ìdìbò Gómìnà àti Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ tó kọjá. Ó ní eléyìí a jẹ́ kí ìjọba fún ọ̀já láti túbọ̀ múra ṣíṣe

Aṣòfin Ọbasá sọ̀rọ̀ yìí nínú ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn tí ó jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò náà padà sí ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó láti tún ṣojú ẹkùn Agege kìíní, tí ẹnì kejì rẹ̀ láti ẹkùn Agege kéjì, Ọ̀gbẹ́ni Jubril Abdulkarim, tí ó ti jẹ́ Alága Ìjọba Ìbílẹ̀ Agege tẹ́lẹ̀ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC náà tún wọlé

Aṣòfin Ọbasá tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ará ìlú náà fún ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) pàápàá ṣáájú ètò ìdìbò àti lásìkò ìdìbò náà.

Ó wòye pé ìfẹ́ tí wọ́n hàn sí ẹgbẹ́ òṣèlú APC fi hàn pé, àwọn olùgbé Èkó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìjọba APC láti pèsè àǹfààní ìjọba Tiwa-n-Tiwa fún wọn lọ́dún mẹ́rin mìíràn. Ó n:

“A dúpẹ́ lówọ́ Ọlọ́run Allah fún àṣeyọrí ẹgbẹ́ òṣèlú wa nínú ètò ìdìbò tó kọjá àti ti Ààrẹ. Mó fi àsìkò yìí dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Agege fún àtìlẹyìn wọn fún ẹgbẹ́ òṣèlú wa.”

“Bákan náà, ni a dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olùgbé Ìpínlẹ̀ Èkó lápapò fún bí wọn ṣe dìbò fún Gómìnà Babájídé Sanwo-Olu fún sáà kejì”

“Ní báyìí tí a ti parí ìdìbò tán, àsìkò ti tó láti fi ẹ̀mí Ìṣọ̀kan múlẹ̀ pẹ̀lú ìdàgbàsókè láàárín ìlú. Eléyìí ni à ó jọ fọwọ́sowọ́pọ̀ ṣe.”

Aṣòfin Ọbasá tún fi múlẹ̀ nínú àpilẹ̀sọ náà èyí tí Alukoro rẹ̀ àgbà, Ọ̀gbẹ́ni Eromosele Ebhomele fọwọ́ sí, pé, Ilé Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó yóò tẹ̀ síwájú láti máa ṣe òfin, àbá àti ìpinnu tí yóò mú ìdàgbàsókè bá Ìpínlẹ̀ Èkó lápapọ̀.

 

Lanre Lagada-Abayomi

Leave A Reply

Your email address will not be published.