Kylian Mbappe dì balógun ìkọ àgbábọ́ọ̀lù Faransé lẹyìn tí balógun tẹlẹ rí Hugo Lloris kéde ìfẹyìntì, àwọn òníròyìn to súnmọ́ ẹgbẹ́ náà sọ.
Àgbábọ́ọ̀lù ọwọ́ iwájú fún Paris Saint-Germain PSG Mbappe, 24, gbà lẹyìn àwọn ìjíròrò pẹ̀lú olukọni Didier Deschamps.
Lloris, ọmọ ọdún mẹ́rindínlógoji 36, àṣọlè ìkọ Tottenham kéde Ìfẹyìntì ní Oṣù Kíní lẹyìn tó pàdánù ìfé àgbáyé ní ọdún tó kọjá lẹyìn tó tí ṣé balógun ìkọ náà ní bí ọdún mẹ́wàá sẹyìn.
Tún kà nípa:WTT: Quadri Ṣẹ́gun Alexis Látí Dé Ìpele Ẹlẹ́ni-Mérìndínlógún
Ọmọ ìkọ Atletico Madrid, Antoine Griezmann ní ìgbákejì balógun náà lẹyìn tí àgbábọ́ọ̀lù ẹ̀yìn ìkọ Manchester United, Raphael Varane náà kéde ìfẹyìntì tirẹ̀ náà lẹyìn ìfé Àgbáyé ọdún tó kọjá.
Mbappe tó tí ṣóju ìkọ náà ni ìgbà mẹ́ridínlàádọ́rin 66, yóò bẹ̀rẹ̀ èrè ìgbábọ́ọ̀lù àkọkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí balógun nínú iperegede sí ìdíje Yúrópù (Euro Qualifier 2024) ní Ọjọ́ Ẹtì pẹ̀lú ìkọ Netherlands ní Stade de France, ní orílẹ̀-èdè náà.
Leave a Reply