Take a fresh look at your lifestyle.

Kefas Agbu Ọmọ Ẹgbẹ́ PDP Bórí Ìdìbò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Taraba

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 208

Àjọ élétó ìdìbò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, INEC tí kéde Kefas Agbu tí ọmọ ẹgbẹ́ (Peoples Democratic Party), PDP gẹ́gẹ́ bí Gómìnà tó bórí ìbò ní ìpínlẹ̀ Taraba lẹyìn tó gbà ìbò tó pọ̀ jùlọ nínú ìdìbò Gómìnà tó wáyé lọ́jọ́ kejidinlogun, oṣù kẹta.

Ọ̀gbẹ́ni Agbu tí gbá ìbò 257,926 látí bórí olùdíje tó sún mọ jùlọ ní olùdíje tí (New Nigeria People’s Party), NNPP Muhammad Yahaya, tó gbá 202,277 nígbà tí ọmọ ẹgbẹ́ (All Progressives Congress), olùdíje APC, Emmanuel Bwacha, gbá 142,502 tí Danladi Baido tí (Social Democratic Party) SDP gbà 28,374.

Alukoro fún àjọ INEC ní ìpínlẹ̀ Taraba, Ọ̀jọ̀gbọ́n Mohammed Abdulazeez àtí Ìgbákejì Chancellor tí Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Abubakar Tafawa, kéde Agbu gẹ́gẹ́ bí Olúbóri ní ọjọ́ Ìṣẹgun.

Tún kà nípa: Ọmọ Ẹgbẹ́ Òṣèlú APC, Umar Namadi Jáwé Olúborí Nínú Ìbò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Jigawa

Agbu bórí àwọn ìjọba ìbílẹ̀ mọkànlá nínú àwọn ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rindínlogún 16 látí jáwé Olúbóri nínú ìdíje náà.

Ọ̀gbẹ́ni Agbu jẹ́ ọ̀gá ológun Nàìjíríà tí ó ti fẹ̀yìn tì, ó sì jẹ́ alága ìjọba ìpínlẹ̀ PDP nígbà kan rí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button