Ààrẹ Muhammadu Buhari tí fí ìbànújẹ́ hàn nípa ikú Hajiya A’isha Rufa’i.
Ìyàáfín Rufa’i jẹ́ Akọ̀wé/Olùdarí tí ààbò Ìlú, Àtúnṣe, Iná àtí ọmọ Ìgbìmọ̀ arínrìn-àjò lábẹ́ ètò abẹ́lé, CDCFIB.
Rufa’i, ní Mínísítà ètò àbẹlé gbóríyìn fún bí “ẹní tó ń ṣiṣẹ́ takuntakun lẹ́nú iṣẹ́” Ó sí ṣé àpèjúwe rẹ̀ gẹgẹ bí “àpẹẹrẹ fún àwọn òṣìṣẹ́” làkókò tó ń rọ̀ àjọ òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ látí “fún u ní ojuse tó gá jùlọ” lẹyìn iṣẹ́ àtúnṣe tó ṣé lórí ilé-iṣẹ́ CDCFIB.
Tún kà nípa:Àwọn Àgbẹ Ìlú Kano Kó Irè Oko Yanturu Ní Àkókò Ọ̀dá Òjò
Nígbà tí Ààrẹ Buhari ń sọ ìbànújẹ́ àti ọ̀fọ̀ rẹ̀, ó rántí àfikún tí olóògbé náà ṣe sí àjọ òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣètò àti alábòójútó tó múná dóko nínú gbogbo àwọn ipa tó ti ṣe tẹ́lẹ̀.
Ó gbàdúrà ìsinmi ẹ̀mí rẹ̀ àti ọkàn akin, ìgboyà fún àwọn ẹbí, àrà àtí ìpínlẹ̀ Kano lápapọ̀.