Àjọ INEC ti kéde ọmọ ẹgbẹ́ All Progressives Congress (APC), Umar Namadi gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó jawe olúborí nínú Ìbò Gómìnà tó wáyé ní ọjọ́ kejìdínlógún ní Ìpínlẹ̀ Jigawa .
Olùkéde ìbò fún ìpínlẹ̀ náà, ọ̀jọ̀gbọ́n Zayyanu Umar Birnin Kebbi ló kéde èyí níbi ètò àkójọpọ̀ ìbò ní ìlú Dutse tíí se olú ìlú Ìpínlẹ̀ náà.
Ó sọ pé, Malam Umar Namadi ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC fi ìbò 618,449 lù àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ní àlùbolẹ̀.
Bí ó se sọ, ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), Namadi Umar Alhaji ní ìbò 618,449, ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP), Lamido Mustapha Sule ní ìbò 368,726 àti ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria Peoples Party (NNPP), Ibrahim Aminu Ringim ní ìbò 37,156 .
Ọ̀gbẹ́ni Namadi yóò dípò Gómìnà tó wà lórí àlééfà lọ́wọ́lọ́wọ́, Abubakar Badaru ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC tí sáà méjì ọdún mẹ́jọ rẹ̀ parí ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn ún, ọdún 2023.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
[…] Tún kà nípa: Ọmọ Ẹgbẹ́ Òṣèlú APC, Umar Namadi Jáwé Olúborí Nínú Ìbò Gómìnà Ìpínlẹ̀ … […]