Àjọ INEC ti kéde ọmọ ẹgbẹ́ APC, Ahmad Aliyu gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó yege nínú Ìbò Gómìnà ti Ìpínlẹ̀ Sokoto
Olùkéde ìbò fún Ìpínlẹ̀ náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n
Armiya’u Hamisu sọ pé ọ̀gbẹ́ni Aliyu borí pẹ̀lú ìbò 45,3661.
Ẹni tó se ipò Kejì wá láti inú ẹgbẹ́ òṣèlú
People’s Democratic Party, PDP, Malam Sai’du Umar, pẹlu ìbò: 40,4632.
Ọ̀gbẹ́ni Aliyu borí nínú ìjọba ìbílẹ̀ mọ́kàndínlógún nínú ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́ta lélógún, alátakò rẹ̀ nínú Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP yege nínú ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà péré.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Hamisu jẹ́ Alákóso Fáfitì ti Àpapọ̀ ní ìlú Dutse, Ìpínlẹ̀ Jigawa .
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san