Olubadan Ilẹ Ìbàdàn kí Gómìnà Seyi Makinde kú oríire fún bí o ṣe jáwé olubori nínú ètò ìdìbò Gómìnà tó kọjá, nígbà tí o lù Ajọ Eleto Ìdìbò INEC ni Ìpínlè náà l’ogo ẹnu fún àṣeyọrí ètò ìdìbò tí ọdún yìí.
Olúbàdàn Ilẹ Ìbàdàn, Oba Lekan Balogun, Allí Okunmade II ló kí Gómìnà Makinde, ẹni tí o jáwé olubori sí ipò Gómìnà léèkejì ní ìpínlè Ọ̀yọ́, kú oríire nigba tí o fi oriire iyansipo rẹ we èrè mímú ìlérí tó ṣe fún àwọn èèyàn Ìpínlè Ọ̀yọ́ ni sáà akọkọ ṣẹ.
Iṣẹ ìkíni kú oríire yìí ní Olúbàdàn fi ranṣẹ sí Gómìnà Makinde nínú atẹjade láti ọwọ Amugbalẹgbẹ rẹ lórí ọrọ ìròyìn, Oladele Ogunsola eléyìí tí o fi s’ọwọ sí àwọn oníròyìn ní ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlè Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Iwọ Oòrùn Orílẹ̀-èdè, ninu eyi ti Oba Balogun ti u Ajo Eleto Ìdìbò, INEC ni Ìpínlè Ọ̀yọ́ fún bí ètò ìdìbò ọhun ṣe lọ lẹsẹsẹ.
Gẹgẹ bíi Oba Balógun ṣe sọ nínú atejade náà nígbà tí o gba Gómìnà níyànjú láti rí ijawe olubori rẹ gẹgẹ bíi àfihàn ìgbàgbọ ti awọn èèyàn Ipinlẹ Ọ̀yọ́ ni ninu rẹ eléyìí tó farahàn nínú iṣẹ réré to ṣe ni sáà akọkọ, to sì rọ ọ láti máṣe fi ojú tẹmbẹlu atilẹyin awọn ará ilu ṣugbọn kò tubọ tẹra mọ iṣẹ rere ni ṣiṣe.
Oba Balogun ṣàlàyé pé, bi o tilẹ je pé o ṣeé ṣe kí agaara ko dá a ni sáà keji yìí nítorí kò fẹ ẹ sí ohun tuntun tó lè gbèrò láti ṣe mọ, ṣugbọn Ọba Balogun rọ Gómìnà láti rí anfààní sáà kejì yìí gẹgẹ bí ọna láti ṣe dáadáa jù sáà akọkọ lọ.
Bákan náà ni Oba Balogun rọ Gómìnà láti fi ọkàn sí àwọn ọrọ àti aleebu tí ẹgbẹ òṣèlú alatako tọka sí lásìkò tí o n ṣe ìpolongo ìbò kò sí ṣe àtúnṣe tí o ba yẹ, nítorí pé kii se gbogbo ọrọ ti ẹgbẹ òṣèlú alatako ba sọ náà ló jẹ aheso ọrọ lati bù ẹnu atẹ lù iṣejọba rẹ, sugbon ti ọpọlọpọ ọrọ wọn n pe àkíyèsí rẹ sì ìṣèjọba rere.
Nígbà tí o gba ádùrá fún àṣeyọrí réré fún Gómìnà ti ìlú dibo yan léèkejì, Oba Balogun pe fún ifowo so’wọpọ tolori tẹlẹmu èèyàn Ìpínlè Ọ̀yọ́, tó sì rọ wọn láti fi òṣèlú di ẹgbẹ kan ki gbogbo wọn ṣiṣẹ poy láì fi ti egbey òṣèlú kan tàbí òmíràn ṣe kí Ìpínlè Ọ̀yọ́ bàa lè gòkè àgbà
Bẹẹ gẹgẹ ni Olúbàdàn gbé oṣuba Kare fún Àjọ Eleto Ìdìbò, INEC fún bí ètò ìdìbò se lo ni irọwọ-rọsẹ, ti wọn sì ṣe àfihàn ìwà Omoluwabi ati ìwà akọṣẹmọṣẹ nínú ètò ìdìbò náà
Abiola Olowe
Ìbàdàn