Take a fresh look at your lifestyle.

Ìperegedé Ìdíje AFCON: Agbábọ́ọ̀lù Simon, Ndidi, Àti Iheanacho Yóò dé sí Ìpàgọ́.

0 101

 

Agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà ní igun lórí pápá, Moses Simon pẹ̀lú Wilfred Ndidi àti Kelechi Iheanacho tí wọn ń gbá böọ̀lù fún ikọ̀ Leicester City yóò tètè dé sí ibùdó ìgbáradì Super Eagle ní Abuja látàrí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ láàrín wọn àti ikọ̀ ti Guinea Bissau láti peregedé fún Africa Cup of Nations(AFCON) ọdún 2024.

Simon tó ń gbá bọọlu fún ìkọ FC Nantes ti Orílẹ̀-èdè Faransé àti Kevin Akpoguma tó ń gbá bọ́ọ̀lù fún ikọ̀ TSG Hoffenheim ni Orilẹ̀-ède Germany yóò jọ dé pẹ̀lú.
Ikọ̀ Super Eagles yóò dé sí ilé ìtura ti JohnWood Hotel ní ìlú Abuja.
Tí wọ́n bá ṣe àṣeyọrí nínú ìdíje méjèèjì, wọ́n ó gba tikẹ̀ẹ̀tì Ìperegedé fún AFCON ẹ̀lẹ́kẹrìnlélọ̀gbọ̀n tí yóò wáyé ní Orilẹ̀-ède Cote d’Ivoire ní ọdún tó ń bọ̀.
Pẹ̀lú Àmì ayò mẹ́fà síi, yóò jẹ méjìlá lápapọ̀ tí wọ́n bá borí.

Ikọ̀ ti orílẹ̀-èdè Sierra Leone leè ní àmì méje tí wọ́n bá borí ikọ̀ ti Sao Tome and Principe. Ikọ̀ Super Eagles máa kojú ikọ̀ Sao Tome and Principe tó wà ní ìsàlẹ̀ Tábìlì ní ìgbà tí wọ́n bá ń fẹsẹ̀wọnsẹ̀ ní ilé ní ìdíje wọn tó parí.

Àwọn agbábọ́ọ̀lù mọ́kàndínlógún tó kù tí wọ́n fi ìwé pè ni ìrètí wà pé wọn yóò dé sí Ìpàgọ́ ní ọjọ́ ajé ogúnjọ́ oṣù kẹta, ọdún 2023.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.