Ògbóǹtarìgì eléré orí ọ̀dàn lágbayé, Tobi Amusan ti bẹ̀rẹ̀ Sáà ọdún yii pẹ̀lú àṣeyọrí nínú eré sísaá Oníbùdó Igba Mítà ti àwọn Obìnrin, ó lo 23.38s láti sá eré náà láti borí Chante Clinkscale tí òun náà sa eré tirẹ̀ ní àkókò 23.56s ní Auburn, Alabama, orilẹ ede USA.
Amusan fi ìtàn balẹ̀ ní ọdún tó kọjá pẹlú ìsẹ́jú méjìlá ó lé die-12.12s ní ibi eré àgbáyé tó wáyé ní Oregon ní ọdún tó kọjá abbl.
Ìrètí wà pé ogbontarigi eléré orí pápá ní àgbáyé náà yóò máa tẹsiwaju nínú àṣeyege rẹ̀ ní ọdún yìí àti sí iwájú síi ní Budapest níbí tí yóò ti máa dáàbòbo àmì ẹ̀yẹ tó ti gbà.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san