Take a fresh look at your lifestyle.

Ọ̀rọ̀ Àkọ́sọ Seyì Makinde Gẹ́gẹ́ Bíi Gómìnà Fún Sáà Kejì Ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

0 123

Lẹyin tí Àjọ Eleto Ìdìbò INEC ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kéde Gómìnà Seyì Makide gẹgẹ bíi ẹni tí o jáwé olubori nínú ètò ìdìbò gómìnà to wáyé ní Àbámẹ́ta ọjọ Kejidinlogun oṣù yìí, Makinde fi ìdùnnú rẹ̀ hàn sí àṣeyọrí náà nígbà tí o n ba àwọn oníròyìn sọrọ.

Nínú ọrọ rẹ, Makinde ni “Nisinsinyi, inú mi dùn gan an. Mo fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn réré Ìpínlè Ọ̀yọ́ fún ìgbàgbọ ti wọn ní nínú ìṣèjọba yìí àti ipá mi láti ṣe àkóso tó laami-laaka.

“Mo sì tún fi àsìkò yìí dupẹ lọ́wọ́ àwọn ọrẹ àti alabaṣiṣẹpọ jakejado orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún ipá ribiribi ti wọn kò ní ọnà kan tàbí òmíràn fún àṣeyọrí ìṣèjọba yìí. Gẹgẹ bíi èrò mi, mo lérò wí pé èrè iṣẹ takuntakun ni láti tẹ síwájú nínú iṣẹ réré.

“Nítorí èyí, fún ìṣèjọba sáà kejì yìí, a o tun ṣe dáadáa síi fún àwọn èèyàn Ìpínlè Ọ̀yọ́ ju bi a ti ṣe ni sáà akọkọ lọ.

“Omituntun 2.0 yóò tún dara, tí yóò sì dùn tí a bá fi wé Omituntun 1.0 lọ. Nítorí èyí, mo kàn fẹ dupẹ lọwọ àwọn aṣáájú, àgbààgbà àti alatilẹyin mi. Mo ya àṣeyọrí yìí s’ọtọ sí Ọlọ́run àti àwọn èèyàn réré Ìpínlè Ọ̀yọ́”

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave A Reply

Your email address will not be published.