Àkójọpọ̀ èsì ìdìbò fún ipò Gómìnà ti ń lọ lọ́wọ́ ní ìlú Maiduguri, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Borno.
Ètò náà ń lọ lọ́wọ́ ní gbọ̀ngàn ilé ẹ̀kọ́ gíga sir Kashim ní ìlú Maiduguri. Níbi tí alákòsóo fún ìpínlẹ̀ náà Ọ̀jọ̀gbọ́n Jude Rabo ti ilé ìwé gíga Yunifásitì tí ó wà ní Wukari ń se adarí.
Lára àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tí wọ́n ti kéde ni Monguno, Hauwul, àti Boha. Tí ìrètí sì wà pé àwọn tókù yóò wọlé láìpẹ́.