Ìjọba ìbílẹ̀ méje ti bẹ̀rẹ̀ ìfiléde èsì ìdìbò wọn ní ìpínlẹ Sokoto
Lára àwọn ìjọba ìbílẹ̀ náà ni Binji, Wurno, Yabo, Isah, Gwadabawa, Tureta, ati Rabah.
Ètò àkójọpọ̀ èsì ìdìbò náà ń wáyé ní ọ́ọ́fìsì àjọ INEC ní ìlú Sokoto níbi tí àwọn asojú ẹgbẹ́ òsèlú, agbófinró àti àwọn akọ̀ròyìn péjú pẹ̀lú wọn.
Alákòsóo ètò ìdìbò ti ìpínlẹ̀ Sokoto, Ọ̀jọ̀gbọ́n Armiyau Hamisu fi àrídájú hàn pé ètò náà yóò lọ láì ní ìfi igbá kan bọ ìkan nínú.