Take a fresh look at your lifestyle.

Adebayo Adelabu Ránṣẹ́ Ẹ kú Oríire Sí Gómìná Seyi Makinde

0 164

Olóyè Adebayo Adelabu ti ẹgbẹ òṣèlú Accord ti ranṣẹ ẹ kú oríire sí Gómìnà Seyi Makinde tí àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ dibo yan láti tù ọkọ ìṣèjọba lẹẹkan síi, tí o sì fi àsìkò náà rọ Gómìnà láti tẹ síwájú nínú iṣẹ réré fún wọn.

Olóyè Adelabu, ẹni tí o ranṣẹ e kú oríire sí Makinde fún bí o ṣe jáwé olubori nínú ètò ìdìbò Gómìnà to wáyé ni ọjọ Kejidinlogun oṣù yìí ló fi idunnu rẹ hàn sí àṣeyọrí rẹ.

Atejade kan tí Adelabu, ẹni tó dije du ipò gómìnà labẹ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú Accord fi ranṣẹ lo sàlàyé wí pé àṣeyọrí yìí jẹ ìpè láti tún ṣe iṣẹ ṣii láti sin àwọn èèyàn Ìpínlè Ọ̀yọ́.

Nínú ọrọ rẹ, Adelabu ní “Ètò ìdìbò ti wáyé o sì ti tẹnu bọ odò, gẹgẹ bí mo ṣe máa n sọ, o yẹ ki gbogbo wa padà sí bí a ṣe n ṣe lateyin wá ni. Ìgbàgbọ mi ni pé, ìdìbò ko gbọdọ jẹ bí o báa-o-pá, bí o báa-o- bu u lẹsẹ, gẹgẹ bí Ọlọrun ṣe máa n yí ìgbà àti àkókò padà, O máa n gbe èèyàn sórí oyè o sì tún máa n rọ èèyàn lóyè bi o ṣe wù. Àkókò Ọlọrun ló dára jù.

O wá tún fi kún ọrọ rẹ̀ wí pé, ìdìbò sí ipò jẹ ọna kan gbógì láti fún ipinlẹ Ọ̀yọ́ ní èrè ìṣèjọba eleyii tí yóò mú ìdàgbàsókè bá ètò ọrọ ajé, igbaye gbádùn àti ọrọ àwọn ará ìlú.

O tun tẹnu mọ àlàyé rẹ nígbà tí o sọ pé, òun kò ní tẹ ti láti máa sín Gómìnà ní gbéré ipakọ lórí àwọn alakalẹ ètò ìṣèjọba, tí o sì tún ṣèlérí pé, ohun tó kù báyìí ni láti fi ọwọ́ so’wọpọ pẹlu Gómìnà láti ṣe aṣeye ti Alakan n ṣe epo.

Bakan náà, Olóyè Adelabu ní “Bí o tilẹ jẹ pé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kò tíì dé ipò tó yẹ kó wà, anfààní míràn ni èyí fún Gómìnà láti ríi dájú pé òun kò já àwọn èèyàn Ipinlẹ Ọ̀yọ́ kulè nípa rí ríi dájú pé ìdàgbàsókè dé tibu tooro Ipinlẹ Ọ̀yọ́.”

O wá tun gba Gómìnà níyànjú láti múra sí ètò ààbò àti ìmọ́tótó àyíká àti agbègbè eléyìí tó n fẹ amojuto ni kankan. Àwọn ilé ẹkọ wa náà nilo amojuto fún ìpèsè àyíká to rọrùn fún àwọn akékòó àti ìpèsè awọn eto idanilẹkọ fún àwọn olùkó ki wọn bàa lè máa ṣe iṣẹ wọn bíi iṣẹ, tí o sì tún fi kún pé ìpèsè iṣẹ fún àwọn ọdọ náà se pàtàkì.

O sì tún ki Gómìnà Seyi Makinde lẹẹkan síi wí pé o kú oríire.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button