Ajọ eleto Idibo INEC ti kede Olùdíje fún ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ All Progressive Congress, (APC), AbdulRahman AbdulRazak gẹgẹ bi oludije to jawe olubori ni ipinlẹ Kwara, ẹkun ariwa orilẹ-ede Naijiria
Alakoso Ibo ni Ipinlẹ naa àti Alakoso fafiti oun ọgbin ni Makurdi, Ọjọgbọn Issac Itodo lo kede yii ni ọjọ aiku lẹyin ti wọn ka ibo gbogbo ijọba ibilẹ mẹrindinlogun tan ni ipinlẹ Kwara
AbdulRazak to jawe olubori ni gbogbo ijọba ibilẹ ipinlẹ naa lo ni ibo 273,424 to fi gbomi ewuro si ara awọn ti wọn jọ dije, oludije ẹgbẹ People’s Democratic Party, (PDP), Shuaib Abdullahi., to ni ibo 155,490.
George Ọláyinká Akíntọ́lá.