Take a fresh look at your lifestyle.

Àbájáde Èsì Ìbò Gómìnà Ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́: Gómìnà Seyi Makinde Ti Ẹgbẹ́ Òṣèlú PDP Jáwé Olúborí Pẹ̀lú Ìbò 563,756

0 185

Èsì ìbò Gómìnà ní àwọn ìjọba Ìbílẹ̀ Mẹtalelọgbọn jakejado Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fi hàn wí pé Gómìnà Seyi Makinde ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lo jáwé olubori.

Gẹgẹ bíi Ọjọgbọn Bamire Adebayo tíì ṣe ọgá àgbà ilé ẹkọ gíga Fasiti OAU, tí o darí àkójọpọ̀ abajade ìbò Gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣe kéde, Gómìnà Seyi Makinde labẹ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló yege ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀ Mọkanlelọgbọ̀n nínú ìjọba Ìbílẹ̀ Metalelọgbọn tó wà ní Ìpínlè Ọ̀yọ́.

Ọjọgbọn Bamirẹ ló sọ èyí di mímọ ní Gbongan Mutiu Agboke tó wà ní ọgbà Àjọ Eleto Ìdìbò INEC ni ìlú ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlè Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Iwọ Oòrùn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, nibi tí o ti kéde Gómìnà Seyi Makinde gẹgẹ bíi Olubori sí ipò Gómìnà lati tù ọkọ ìṣèjọba Ìpínlè Ọ̀yọ́ fún ọdún Mẹrin míràn.

Gẹgẹ bíi abajade èsì ìbò náà ṣe fi hàn, apapọ ìbò ti àwọn oludibo dì (TVC) jẹ 889,592, tí apapọ ìbò tí awọn oludibo dì lónà ẹtọ jẹ 874,672, tí apapọ ìbò ti wọn dì lónà àìtó (RV) sí jẹ 14,920, nínú èyí tí Olóyè Adebayo Adelabu labẹ ẹgbẹ òṣèlú Accord ni ìbò 38,357; Aṣòfin Folarin Teslim labẹ àsìá ẹgbẹ òṣèlú APC ní ibo 256,685; Akinwale Taofeek tí ẹgbẹ òṣèlú LP ni ìbò 1500; ti Makinde Seyi tí ẹgbẹ òṣèlú PDP sí ní ìbò 563,756.

Nígbà tí o n fi idunnu rẹ hàn sí abajade ìbò Gómìnà náà, Ọmọwe Nureni Adeniran ti o jẹ aṣoju ẹgbẹ òṣèlú PDP ati Gomina Seyi Makinde fún akojọpọ èsì ìdìbò náà fi da àwọn èèyàn Ìpínlè Ọ̀yọ́ lójú pé Gómìnà Makinde ko ní já wọn kulẹ, sugbon yóò tún ṣe dáadáa jù ní o ti ṣe ni sáà akọkọ.

Bákan náà ni ẹni tíì ṣe akọwe ẹgbẹ òṣèlú APC ni Ìpínlè Ọ̀yọ́ tó sojú ẹgbẹ òṣèlú APC nínú akojọpọ èsì ìbò Gómìnà je kí o di mímọ pé òun kò lodi sí abajade esi ìbò náà tó di jẹri síi pé òhun gbogbo ló lọ ní irọwọ-rọsẹ.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button