Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ní Ìgbàgbọ́ Pé Ẹgbẹ́ Òṣèlú APC Yóò Borí

0 93

Ààrẹ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ìjọba àpapọ̀ , Ahmad Lawan gbàgbọ́ pé ẹgbẹ́ Òṣèlú All Progressives Congress, APC yóò ṣe àseyege ókéré tán nínú ìpínlẹ̀ méjìdínlọ́gbọ̀n nínú ìbò Gomina àti ti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti ìpínlẹ̀.

Sénétọ̀ Lawan sọ èyí nígbà tí o ń dáhùn ìbéèrè láti ọ̀dọ̀ àwọn oníròyìn ní Wọ́ọ̀dù
Katuzu ní ìjọba ìbílẹ̀ Bade ni ìpínlẹ̀ Yobe lẹ́yìn tí ó dìbò rẹ̀

Ó so wí pé ” Ìdìbò ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, a ti gba ìṣàkóso rẹ̀, a sì ti borí nípa ti ìdìbò tí Ààrẹ. Ìpínlẹ̀ méjìdínlọ́gbọ̀n o kéré tán ni a o ti jáwé Olùborí ní òpin ibò yìí”.

Ó tún sọ pé, Egbe APC ló ń ṣàkóso lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ mọ́kànlélógún nínú ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì, ó ti jáwé Olùborí nínú ìpínlẹ̀ méjìlá báyìí. Ó fi kún pé ẹ̀rò BVAS ń ṣiṣẹ́ dáradára ní ìjọba ìbílẹ̀ òun, inú òun sì dùn sí èyí.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.