Take a fresh look at your lifestyle.
Election

Japan, South yóò pawọ́pọ̀ láti Kojú ìpeniníjà ààbò agbègbè

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 92

Àwọn adarí orílẹ̀-èdè Japan àti South Korea ti pinnu láti ṣiṣẹ́ papọ̀ fún ìkojú ìpeniníjà ààbò agbègbè.

Àwọn adarí méjèèjì pinnu láti fòpin sí ìkóríra ààrin wọn níbi àpèjọ kan, ní Ọjọ́bọ̀,láàrin Yoon Suk Yeol ti South Korea àti Fumio Kishida ti Japan ní Tokyo – àbẹ̀wò alákọ̀ọ́kọ́ ààrẹ South Korea sí Japan ní ọdún méjìlá.

Inú Washington dùn sí àpèjọ náà, tí sì ó ṣàpèjúwe Japan àti South Korea gẹ́gẹ́ bíọ̀rẹ́ tí  kò ṣeé mánìí”.

Làásìgbò  Seoul-Tokyo ti fa ìfàṣẹ́yìn akitiyan Amẹ́ríkà láti pẹ̀tù sí  China àti North Korea.

Ìtan ogun ti jẹ́ kí Ìbáṣepọ̀ tó mẹ́hẹ wà láàrin wọn,àti lórí ẹ̀san iṣẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ South Korea lábẹ́ iṣẹ́ Japan 1910-1945, pẹ́lú ọ̀rọ̀ mímú àwọn obìnrin àti ọ̀dọ́ bìnrin nípá lọ sí ilé ìtura àwọn ọmọ ológun Japan.

Leave A Reply

Your email address will not be published.