Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Èkó nílò àdúrà àti ìsapá fún ìṣòkan àwọn olùgbé ibẹ̀ lẹ́yìn ètò ìdìbò- Àáfà Àgbà kan

0 68

Olori agba fun Ijọ Ansar-Ud-Deen Society of Nigeria, Sheikh Abdur Rahmon Ahmad sọ pe erongba akọkọ fun ẹnikẹni to ba wọle gẹgẹ bi Gomina ni Ipinlẹ Eko ni ọna lati fi ẹmi iṣokan mulẹ pada laarin awọn olugbe ibẹ, eleyii to sọ pe, ọrọ eto idibo yii ti ṣokunfa iyapa laarin awọn ẹya ati ẹsin.

Aafa agba Musulumi naa sọrọ iṣiti yii ninu eto adura pataki ti Ijọ Elẹsin Musulumi Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ṣagbatẹru rẹ ninu mọṣalaṣi gbagede ile aṣofin naa, eyi ti wọn ṣe lati fi beere pe, ki eto idibo to n bọ lọ ni irọwọ irọsẹ laisi laasigbo kan. O ni Gomina to ba wọle gbọdọ fi ẹmi iṣọkan mulẹ lẹyin eto idibo yii.

Sheikh Ahmad ro gbogbo ara ilu ti wọn lanfani lati dibo ki wọn jade lati dibo ni ọjọ Abamẹta (Satide) naa nitori o jẹ ojuṣe ẹnikọọkan labẹ ofin, o si tọna niwaju Ọlọrun. O ni:

“Ki gbogbo ẹni to ba ti to ibo di, ki wọn jade lati lọ dibo, nitori ko si ‘pin temi demi’. Ki koowa o jade lati dibo, lati le ni ẹnu lati sọrọ lọjọ ọla. Ki wọn o dibo fun ẹni to tọ, ẹni ti o yẹ. Ki wọn dibo fun ẹni o tọ, ti yoo ṣe deedee pẹlu wọn.”

Bakan naa lo rọ ijọba Ipinlẹ Eko lati wa ojutu si iṣoro gbigba owo ti ko tọ lọwọ awọn ara ilu, paapaa awọn ‘agbero’ ati awọn ẹṣọ ijọba bi, LASTMA n gba. O ni:

“Ijọba ni lati wa ojutu si ọrọ awọn agbero ni Ipinlẹ Eko, paapaa bi wọn ṣe n fara ni awọn ara ilu. Ki ijọba o ṣatunṣe si awọn owo-orí ti wọn n gba paapaa awọn to n ni awọn ara ilu lara ni Ipinlẹ Eko. Gbogbo ohun ti Ajọ LASTMA n ṣe niisinyi ko gbọdọ jẹ ẹtan, ki wọn le dibo fun ijọba to wa lori aleefa. Amọ ki wọn ri i gẹgẹ bi ọna to yẹ ki wọn maa ṣe lati fi maa ṣiṣẹ wọn. Wọn gbọdọ jawọ ninu rireti pe, ki ẹnikan ṣẹ si ofin irinna ki wọn le fọwọ ofin mu u. Wọn o gbọdọ ri awọn ẹṣẹ bayii gẹgẹ ọna ati maa gba owo sapo ijọba.”

Ninu ọrọ rẹ, Akọwe-agba Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Olalekan Ọnafẹkọ rọ awọn ara ilu paapaa awọn ondibo lati yago fun wahala ati ijọgbọn ninu eto idibo naa, ki eto idibo yii le waye ni irọwọ-irọsẹ. O ni:

“Mo rọ awọn ara ilu lati maa fa wahala ninu eto idibo naa, ki wọn ranti pe lẹyin idibo a ni lati bara wa gbe pẹlu ifẹ nitori pe, ọpọ wa ko ni ibomiran ti a le lọ lẹyin Eko yii. Fun idi eyi a ni lati tun ibẹ ṣe, Eko ò ni bajẹ o”

Ẹwẹ, Imaamu Agba Moṣalaṣi Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Imaamu Abdul Shakur Oshoala tẹnu mọ pataki Eto Adura Pataki ti Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko gbe kalẹ naa, lati fi ṣina alaafia fun eto idibo Gomina ati Ile Igbimọ Aṣofin ni Ipinlẹ Eko, ati pe, ki alaafia to ti n jọba lati ọpọ ọdun sẹyin le tẹ siwaju ni Ipinlẹ Eko.

Leave A Reply

Your email address will not be published.