Take a fresh look at your lifestyle.
Election

Inú Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Dùn sí bí Ètò Ìdìbò ṣe ń lọ ní Ìrọwọ́-Rọsẹ̀ 

0 54

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ, Ọ̀gbẹ́ni Seyi Makinde ti fi ìdùnnú rẹ̀ hàn pẹ̀lú àríwòye pé ètò ìdìbò láti yan Gómìnà àti àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin se ń lọ déédé ní ìpínlẹ̀ náà.

 

Ó fi ìdùnnú rẹ̀ hàn sí ètò náà nígbà tí ó ń dìbò ní ibùdó ìdìbò ti wọ́ọ̀dù ẹlẹ́ẹ̀kọkànlá, ìpín alákọ̀kọ́ọ́ ní àgbègbè Abayọmi, ìlú Ìbàdàn.

 

Gómìnà fi àsìkò náà lu àwọn agbófinró lọ́gọ ẹnu fún akitiyan wọn láti ríi dájú pé ètò náà kẹ́sẹ járí.

Leave A Reply

Your email address will not be published.