Ètò idibo ti bẹrẹ ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Ní ìjọba Ìbílẹ̀ Ìlà Oòrùn Àríwá Ìbàdàn tí Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Seyi Makinde ti ẹgbẹ òṣèlú PDP ti dibo, àwọn oṣiṣẹ Àjọ Eleto Ìdìbò, INEC dé ibùdó ìdìbò náà lásìkò ti ètò àyẹwò oludibo pẹlu ẹrọ ayẹwo BVAS sí n lọ nígbà tí àwọn oludibo sí n dibo bákan náà.
Nígbà tí o n ba àwọn oníròyìn sọrọ lẹyìn tí o dibo rẹ tán ní ibùdó ìdìbò 001 ní Wọọdu 11, Makinde fi ẹmi imoore hàn sí àwọn èèyàn ìpínlè Ọ̀yọ́ fún bí wọn ṣe tú yaaya jáde láti dibo, o wa fi àsìkò náà rọ gbogbo awọn èèyàn tí kò ti jáde láti dibo ki wọn yàrá láti ṣe bẹẹ.
Bákan náà, ni Ìjọba Ibilẹ Ariwa Ìbàdàn ní ibùdó ìdìbò 022, ni Wọọdu Kẹta (3), Òkè-Aremo tí Aṣòfin Sarafadeen Abiodun Alli ti ẹgbẹ òṣèlú APC, ẹni tó jáwé olubori gẹgẹ bíi Aṣòfin ti yóò ṣojú Ẹkùn Ìdìbò Gúsù Ọ̀yọ́ nínú ìdìbò gbogboògbò to wáyé ni ọjọ Karundinlogbon oṣù Kejì ọdún yìí tí dibo, ètò ìdìbò náà lọ ní irọwọ-rọsẹ ti ẹrọ BVAS náà sì n ṣiṣẹ bo ti tọ àti bí o ti yẹ.
Ní ibùdó ìdìbò 001, Wọọdu kẹwàá (10) tó wà ní Ẹlẹrọ-Mẹta ni Ìjọba Ibilẹ Ariwa Ìbàdàn tí Oludije du ipò Gómìnà labẹ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP, Adepọju Joshua Popoola ti dibo, ètò ìdìbò lọ leto leto tí àwọn ẹṣọ eleto aabo náà sì wá lójú iṣẹ láti pèsè ààbò tó péye.
Abiola Olowe
Ìbàdàn