Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàíjíríà yóò dìbò Gómìná Tuntun Àti Àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀

George Ọláyinká Akíntọ́lá

0 168

Omọ orílẹ̀-èdè Nàíjíríà tó tó mẹ́tàléláàdórùn mílíónù ní yoo yan àwọn Gomina ipinlẹ tuntun àti àwọn aṣòfin ní òní Ọjọ́ Satidee ọjọ kejidinlogun, ọdun 2023.

 

Ọjọ́ kọkanla osu kẹta lo ye ki idibo yii ti waye gẹgẹ bi ọrọ àjo eleto idibo orílẹ̀-èdè Nàíjíríà INEC, ṣùgbọ́n wọn sun siwaju nitori atunto àti atunse ẹrọ BVAS.

 

Ẹ̀rọ BVAS ni àjọ INEC yóò fi ṣe àyẹ̀wò orúkọ, idibo àti gbígbé àbájáde idibo. Ẹrọ naa nṣiṣẹ pẹlu kaadi SIM lori eyikeyi nẹtiwọọki alagbeka. Awọn ẹgbẹ Awujọ Ilu ti ṣiṣẹ ni imunadoko pẹlu Igbimọ Ajọ Eleto Idibo, INEC àti àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú lati ri daju pe, o ṣe rẹ́gí.

 

Ìdìbò Gómìná kii yoo waye ni ipinlẹ mẹjọ ninu awọn ipinlẹ merindinlogoji àti Federal Capital Territory, FCT. Awọn ipinlẹ naa niwọnyi; Ekiti, Kogi, Edo, Bayelsa, Anambra, Ondo, Imo àti Ipinlẹ Osun, ṣugbọn idibo aṣofin Ipinlẹ yoo waye ni awọn ipinlẹ mẹjọ yii àyàfi olu-ilu orilẹ-ede Naijiria, FCT.

 

George Ọláyinká Akíntọ́lá

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button