Take a fresh look at your lifestyle.
Election

Àwọn Olùdíje fún ipò Gómìnà lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ Òṣèlú PDP, ACCORD Àti SDP Ti Dìbò Wọn Ní Ìpínlẹ̀ Rivers

0 59

Olùdíje fún Ipò Gómìnà lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Siminalayi Fubura àti ìyàwó rẹ̀ di ibò wọn ní Ibùdó Keji, Wọ́ọ̀dù Karùn ún, ìlú Opobo, ìjọba ìbílẹ̀ Opobo/Nkoro, ipinle Rivers.

Ọ̀gbẹ́ni Fubura nígbà tí ó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, ó sọ pé òun wòye pé òun yóò jáwé Olúborí látàrí àtìlẹ́yìn àwọn ènìyàn.

Bakanna, Olùdíje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Accord , Dumo Lulu-Briggs náà di ìbò tirẹ̀ ní ibùdó ìdìbò Abonnema ní Ìpínlẹ̀ Rivers.

 

Nígbà tí ó bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ní kété tó di tán, ó ní òun lu àwọn àjọ INEC ni ọ̀gọ ẹnu fún ètò náà tí wọ́n jẹ kó rọrùn, Ó sọ pé inú òun dùn fún àwọn ènìyàn tí wọ́n jáde ní yanturu.

 

Sẹ́nétọ̀ Magnus Abe ti ẹgbẹ́ òṣèlú Social Democratic Party SDP náà di ibò tirẹ̀ ní ibùdó ìdìbò Ogoni, Ó rọ àjọ INEC láti jẹ́ kí ètò náà kẹ́sẹjárí láì sí ẹ̀rù kankan. Ó dun inú sí àwọn Olùdìbò ti wọ́n wá láti ṣe ojúṣe wọn

Leave A Reply

Your email address will not be published.