Take a fresh look at your lifestyle.

Àbájáde Ìdìbò Gómìná Àti Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́: Makinde jáwé Olubori Ní Ibùdó Ìdìbò Rẹ̀

0 217

Gẹgẹ bí àbájáde ìdìbò Gómìnà àti ilé Ìgbìmò Aṣòfin Ìpínlè ṣe bẹrẹ lẹyìn tí ìdìbò parí, Gómìnà Seyi Makinde ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP jáwé olubori ní ibùdó ìdìbò rẹ.

Nígbà tí oṣiṣẹ Àjọ Eleto Ìdìbò to mójú tó ètò idibo ati kíka èsì àbájáde rẹ ni ibùdó ìdìbò ti Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti dibo, àbájáde ìdìbò fi hàn pé ẹgbẹ òṣèlú PDP ní ibo 174, ti ẹgbẹ òṣèlú APC ní ibo Mejidinlọgbọn, tí ẹgbẹ òṣèlú LP sì ni ibo Mẹta (03)

Bákan náà, ni ẹgbẹ òṣèlú PDP rí ìbò Ogojo (160), nígbà tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC rí ìbò Ọgbọn (30), ẹgbẹ òṣèlú Accord rí ìbò Mẹsan (9), tí ẹgbẹ òṣèlú LP sì rí ìbò Márùn ùn (5).

Makinde, ni o tí lọ dibo ni ibùdó ìdìbò 001, ni Wọọdu Kọkànlá (11), ni agbègbè Abayomi Iwo-Road, Ìjọba Ibilẹ Ìlà Oòrùn Àríwá Ìbàdàn ní déédé aago Méwàá kọja isẹju Mejidinlogoji (10:38am)
owurọ yìí.

 

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave A Reply

Your email address will not be published.