Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Jìgáwá: INEC gbaradì fún ìbò gómìnà,ìgbìmọ̀ ilé aṣojú ṣòfin

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 103

Ìgbìmọ̀ olómìnira tó ń mójútó ètò ìdìbò lórílẹ̀-èdè INEC,ti sọ pé òun ti gbaradì fún ìdìbò gómìnà àti ilé ìgbìmọ̀ aṣojú ṣòfin tí kò lábààwọ́n ní ìpínlẹ̀ Jìgáwá.

Kọmiṣọna INEC ti ipinlẹ naa, Ọjọgbọn Muhammad Bashar sọ eyi ni ọjọ Ẹti, nigba ti o n ba awọn akọroyin sọrọ ni olu ile-iṣẹ INEC,ni Dutse, olu-ilu.

Ó túnbọ̀ ṣàlàyé pé wọ́n ti kó gbogbo àwọn oun èlò ṣe kókọ́ àti tí kò ṣe kókó lọ sí ààyè oníkálukú wọn láàrin ìlú,fún àwọn olùdìbò mílíọ́nù méjì tó forúkọ sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà.

Mohammed sọ pé wọ́n ti ṣe ìdánilẹ́ẹ́kọ̀ tuntun fún àwọn òṣìṣẹ́ ìdìbò àti àwọn olùkàbò láti túnbọ̀ jẹ́kí iṣẹ́ wọn ó gún régé ní ọjọ́ Àbámẹ́ta.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.