Take a fresh look at your lifestyle.

ÌPÍNLẸ̀ JIGAWA: ÀJỌ ELÉTÒ ÌDÌBÒ TI GBÁRADÌ FÚN ÈTÒ ÌDÌBÒ GÓMÌNÀ ÀTI ILÉ ÌGBÌMỌ̀ AṢÒFIN

Ademola Adepoju. Dutse

0 162

Àjọ elétò ìdìbò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà (INEC) ti fi han pe oun ti setan lati ri pe eto idibo gomina ati ile igbimọ aṣofin ní ipinlẹ Jigawa lọ ni irọwọ ati irọsẹ.

Kọmisana Idibo ti Olugbe to n dari ipinlẹ naa, Mohammed Bashar lo sọ eyi lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni olu ile-iṣẹ ajọ INEC niluu Dutse olu ilu ipinlẹ naa.

Gẹgẹ bi Mohammed ṣe sọ, “Mo fẹ ko wa ni akọsilẹ pe Ipinlẹ Jigawa ti mura silẹ ni kikun fun idibo Gomina ati Ile-igbimọ Aṣofin. A ti gbe gbogbo awọn ohun elo ti yoo mu ki aṣeyọri bá idibo ọla, ọjọ kejidinlogun, osu kẹta ọdun, 2023 sibi to yẹ ko wa.

O salaye siwaju pe gbogbo awọn ohun elo ti o ni itara ati eyi ti ko ni itara ni a ti gbe lọ si awọn ipo oriṣiriṣi laarin ipinlẹ naa. “A ti pin awọn ohun elo ti o ye si gbogbo awọn agbegbe ijọba mẹtadinlọgbọn ti ipinlẹ naa. A ti ṣe idanwo ati pinpin awọn ẹrọ (BVAS) to to ẹgbẹrun mẹrin lọ si gbogbo awọn agbegbe idibo lati ri daju pe o to fun awọn oludibo tó tó milionu meji ti wọn forukọsilẹ ni ipinlẹ naa

Mohammed tun fi kun pe wọn ṣe atunyẹwo ẹkọ fun awọn oṣiṣẹ idibo ati awọn oṣiṣẹ akojọpọ lati mu aseyori ba idibo ọjọ abamẹta

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button