Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdìbò: Igbákejì ààrẹ Ọ̀ṣínbàjò gúnlẹ̀ sí Ikenne, ìpínlẹ̀ Ògùn

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 90

Igbákejì ààrẹ Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ymí Ọ̀ṣínbàjò , àti ìyàwó rẹ̀, Dlápọ̀,ti gúnlẹ̀ sí Ikenne,ìpínlẹ̀ Ògùn,ní ọjọ́ Àbámẹ́ta,fún ìdìbò gómìnà àti ti ilé ìgbìmọ̀ aṣojú ṣòfin ìpínlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmí Ọ̀ṣínbàjò , àti ìyàwó rẹ̀, yoo dibo ni ibudo idibo kẹrinla, Egunrege  ní ìjọba ìbílẹ̀  Ikenne.(LGA).

Ikenne jẹ ilu Igbákejì ààrẹ Ọ̀ṣínbàjò . Ìpínlẹ̀ Ògùn jẹ́ ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ tí ìbò gómìnà yóò ti wáyé ní ọjọ́ Àbámẹ́ta.

Ikenne, tí ó tún jẹ́ olú ìlú ìjọba ìbílẹ̀ Ikenne LGA, jẹ́ ìlú pàtàkì nínú ìtàn  Nàìjíríà,nítorí pé àwọn ènìyàn pàtàkì nínú òṣèlú Nàìjíríà àti àwọn tó gbajúmọ̀ láwùjọ jáde níbẹ̀.

Olórí gúsù iwọ̀ oòrùn Nàìjíríà tẹ́lẹ̀,Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ wá láti Ikenne.  Awólọ́wọ̀ jẹ́ bàbá bàbáa ìyàwó igbákejì ààrẹ.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.