Ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń ṣèjọba, All Progressives Congress (APC) àti People’s Democratic Party (PDP), ní ìpínlẹ̀ Èkó ti kéde ìfòpin sí ìpolongo fún ìbò gómìnà àti ilé ìgbìmọ̀ aṣojú ṣòfin,ní ọjọ́ Àbámẹ́ta,ọjọ́ kejìdín-lógún.
Gẹ́gẹ́ bí òfin àti ìlànà tí ìgbìmọ̀ olómìnira ètò ìdìbò (INEC), fi lélẹ̀,gbogbo ìpolongo gbọ́dọ̀ wá sópin ní wákàtí mẹ́rìnlé-lógún kí ó tó di ọjọ́ ìdìbò.
Agbẹnusọ fún àwọn ẹgbẹ́ méjéèjì ṣe ìkéde yìí nínú àlàyé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní Ọjọ́bọ̀,ní Èkó,iwọ̀ oòrùn Nàìjíríà.
Akọ̀wé ipolongo APC ìpínlẹ̀ Èkó, Ọ̀gbẹ́ni Ṣẹ̀yẹ Ọládẹ̀jọ, sọ pé ẹgbẹ́ náà ti mú ìpolongo rẹ̀ wá sópin.