Ìdìbò gómìnà: Agbófinró ṣe ìhámọ ́lílọ bíbọ̀ ọkọ̀ ní ìpínlẹ̀ Borno
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ikọ̀ Agbófinró ìpínlẹ̀ Borno, ilá-iwọ̀ oòrùn Nàìjíríà ti sọ pé ìhámọ ́lílọ bíbọ̀ ọkọ̀ lásìkò ìdìbò gómìnà àti ti ìgbìmọ̀ ilé aṣòju ṣòfin ìpínlẹ̀ yóò wà,ní ọjọ́ Abámẹ́ta,ọjọ́ kejìdín-lógún,ní ìpínlẹ̀ náà.
Kọmíṣọ́nà fún àwọn Agbófinró ti ìpínlẹ̀ Borno , Ọ̀gbẹ́ni Abdu Umar tí ó ṣe ìkéde yìí, sọ pé ìhámọ́ yóò wà fún onírúurú lílọ bíbọ̀ ọkọ̀ àti ìrìnnà láàrin ìpínlẹ̀.
Kọmíṣọ́nà náà tún wá pinnu ìbò tí kò lábààwọ́n, tí ó sì jẹ́ tòdodo.
Ọ̀gbeni Umar sọ pé àwọn oṣìṣẹ́ elétò ìdìbò bíi òṣìṣẹ́ INEC, àwọn awòye àti àwọn ọkọ̀ tí wọ́n fi ń gbé aláìsàn lásìkò pàjáwìrì àti àwọn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ pàtàkì nìkan làyè gbà láti rìn láìsi ìdíwọ́ kankan.