Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárì ti gúnlẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Katsina láti dìbò gómìnà àti ti ilé ìgbìmọ̀ aṣojú ṣòfin ìpínlẹ̀ ,ọdún 2023.
Ààrẹ gúnlẹ̀ ní dédé agogo mẹ́ta kọjá ogún ìṣẹ́jú ìrọ̀lẹ́,sí pápá òfurufu káríayé Umaru Yar’Adua Katsina.
Ọwọ́ọ Gómìnà, Àmínù Másàri àti àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ ìpínlẹ̀ ni ó dé sí.
Ààrẹ wá wọ ọkọ̀ ojú-omi lọ sí Dàùrá, níbi tí yóò ti dìbò rẹ̀ ní ọjọ́ Àbámẹ́ta.