Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Nàìjíríà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn gbimọ ìjọba àpapọ̀ tó kúnjú òsùnwọ̀n

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 88

Ààrẹ Nàìjíríà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, Bọ́ĺa Tinubu, sọ pé ìpinnu tí òun ní ni láti pèsè ìjọba àpapọ̀ tó kúnjú òsùnwọ̀n,yàtọ̀ sí ti ìṣọ̀kan orílẹ̀-èdè láti gbọ́ ti ìpeniníjà orílẹ̀-èdè.

Ààrẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, Tinubu sọ èyí nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan ní Ọjọ́bọ̀,ní  Àbújá.

Ààrẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, Tinubu tún sọ síwájú pé kò sí ìdí kankan láti tún máa padà sí àìgbọ́yè àwọn ọdún tó ti kọjá.

Ààrẹ tó ń bọ̀ lọ́nà wá pinnu pé, àwọn ọ̀dọ́ yóò wà nínú  ìgbìmọ̀ aláṣẹ òun,òun yóò sì gba àwọn obìnrin láyè àti pé ìkúnjú òsùnwọ̀n yóò ṣe pataki,yàtọ̀ sí ẹ̀sìn.

Ó wá gbàdúrà pé lábẹ́ ìṣàkóso òun,àwọn ọmọ Nàìjíríà yóò le gbé ìgbé ayé tó ní ìmọ́lẹ̀ àti ìrọ̀rùn àti ìlọsíwájú tó gbòòrò.

Leave A Reply

Your email address will not be published.