Ààrẹ oriĺẹ̀-èdèTanzania Saluhu Hassan, ti pè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ètò ààbò àti kár̀a kátà pẹ̀lú South Africa.
Hassan, ààrẹ bìnrinTanzania àkọ́kọ́ , ṣèpàdé pẹ̀lú ààrẹ orílẹ̀ -èdè South African, Cyril Ramaphosa,ní olú ìlú,ní Ọjọ́bọ̀,níbi tí ìgbìmọ̀ aṣojú aláṣe àpapọ̀ ti jíròrò lórí àǹfàní kát̀a kárà àti ìfẹnukò pẹ̀lú ẹnìkejì rẹ̀, ti South Africa.
Eléyìí jẹ́ àbẹ̀wò alákọ̀ọ́kọ́ Hassan sí South Africa láti ìgbà tó ti di ààrẹ Tanzania,lẹ́yìn ikú ẹni tí ó kúrò lórí oyè, John Magufuli ní 2021,kí òun tó bọ́ síbẹ̀.
Ó fi kun pé ìrìnàjò afẹ́ àti ẹ̀ka ilé iṣẹ́ tó ń ṣe ǹkan títà ló ta wọ́n yọ nínú ẹ̀ka ìdókòwò.
Ramaphosa sọ pé, iye kárà kátà tó wà láàrin Tanzania àti South Africa túnbọ̀ ń pọ̀ sini ṣùgbọ́n ó tún le ní ìgbéga síwájú.