Gbajugbaja àgbábọ́ọ̀lù ẹlẹ́yìn lórí tábìlì tí Nàìjíríà, Quadri Aruna, Ṣẹ́gun Alexis Lebrun ọmọ orílẹ̀-èdè France, ní àmì ayò 3-2 nínú ìdíje àgbáyé “World Table Tennis Championship 2023” tí àwọn Ọkùnrin tó ń lọ́ lọ́wọ́ bí ó ṣé yégé sí ìpele ẹlẹni merindinlogun (round of 16) ní orílẹ̀-èdè Singapore.
Quadri ní ìjakúlẹ̀ nínú ìdíje náà ní ọdún 2022 ní ìpele ẹlẹni méjì lé lọ́gbọ́n (round of 32), ṣùgbọ́n ó bórí ìpele náà ní ọdún yìí pẹ̀lú àmì ayò 3-2 (8-11, 11-8, 11-5, 7-11 àtí 11-7) bí ó ṣé peregede sí ìpele náà.
Tún kà nípa:Quadri Dúpẹ́ Fún Àtìlẹyìn Aláìláfiwé
Quadri, àgbábọ́ọ̀lù ẹlẹ́yìn lórí tábìlì náà ní akọ́kọ̀ ní ilẹ̀ Áfíríkà, ní ọkùnrin ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tó ṣẹ́ku nínú ìdíje náà lẹ́yìn tí ògọọrọ ọmọ orílẹ̀-èdè Egypt bí Omar Assar, Dina Meshref, Hana Goda àtí Mariam Alhodaby tí jáde ní ìbẹrẹ ìdíje.