Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdìbò Gómìnà Àti Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀: Ẹ Ṣíwọ́ Iṣẹ́ Ní Aago Méjìlá Ní Ọjọ́ Ẹtì – Makinde

0 122

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti kéde fún gbogbo oṣiṣẹ ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti ṣiwọ iṣẹ ní aago Méjìlá ọsan ni Ẹtì, ọjọ́ Kẹtadinlogun oṣù yìí.

Ìkéde yìí ló jẹyo nínú atẹjade tí Akọwe Ìjọba, Olubanwo Adeosun bu ọwọ lù, ni ònà láti fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ni Ìpínlè Ọ̀yọ́ ti yóò bá rin ìrìn àjò ní igbaradi fún ètò ìdìbò Gómìnà àti ilé Ìgbìmò Aṣòfin, tí yóò wáyé ni ọjọ́ Àbámẹ́ta (18/03/2023) ní anfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Bákan náà ni atẹjade náà tún sàlàyé wí pé, àwọn òṣìṣẹ́ tó wà ní agbọn iṣẹ pàtàkì nìkan ni yóò máa tẹsiwaju pẹlu iṣẹ wọn nígbà tí àwọn oṣiṣẹ yòókù yóò ṣiwọ iṣẹ ní aago méjìlá ọsan ọjọ́ Ẹtì.

Gẹgẹ bíi ìkéde nínú atẹjade náà, Gómìnà rọ gbogbo oṣiṣẹ ìjọba jakejado Ìpínlè Ọ̀yọ́ láti tu yaaya jáde ní ọjọ́ Àbámẹ́ta láti ṣe ojúṣe wọn gẹgẹ bíi oludibo.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave A Reply

Your email address will not be published.