Ààrẹ Muhammadu Buhari sọ́ wípé iyalẹnu ló jẹ́ fún òún látí gbọ́ pé àwọn ẹsìn-ó-kọ́ku tún ṣé ikọlù ìpànìyàn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀mí aláìṣẹ ní ìjọba ìbílẹ̀ Zangon Kataf ní ìpínlẹ̀ Kaduna.
Ààrẹ Buhari sọ pé kí àwọn òṣìṣẹ́ Ilé-iṣẹ́ Ààbò àtí Ilé-iṣẹ́ Ọlọ́pàá ṣé àwárí àwọn oníṣe làabi yìí látí fí òpin sí irúfẹ́ iṣẹ̀lẹ̀ bẹ̀ẹ̀.
Ààrẹ tún fí ẹdùn ọkàn rẹ̀ hàn sí àwọn ìdílé, ọrẹ atí ojúlùmọ̀ tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọ́n nínú ìkọlù náà. “Kí Olùwà tẹ́wọ̀n sí afẹ̀fẹ̀ réré.”