Alákòsóo àjọ tí ó ń mójútó ọ̀rọ̀ oúnjẹ àti òògùn lílò, NAFDAC, Ọjọgbọn Christianah Adeyẹye ti sọ wípé, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kò ní se lílo igbó lẹ́tọ̀ọ́ àyààfi fún ìpèsè òògùn tí ó wà fún ìtọ́jú àìsàn ara, gẹ́gẹ́ bí ìjọba se korò ojú sí gbíngbìn àti lílò rẹ̀ ní ọ̀nà àìtọ́.
Ó sàlàyé síwájú pé, ó wà lára ojúse àjọ náà láti ríi dájú pé táábà náà wà fún lílò nípa ìpèsè òògùn nìkan, tí kò sì fi àyè gba ẹnikẹ́ni láti lò ó ní ọ̀nà àìtọ́. Ó wá fi ìpinnu hàn pé ìjọba kò ní fi ọwọ́ sí ìpèsè rẹ̀ fún àwọn aráìlú, nítori pé ọ̀nà àti pinwọ́ lílò rẹ̀ fún ìwà ìbàjẹ́ kò rọrùn fún ìjọba Nàìjíríà.
Àjọ àgbáyé tí ó ń rí sí ìsàkóso òògùn lílò náà se àfiléde nípa àmójútó tí ó péye fún àrídájú lílo òògùn lọ́nà tí ó tọ́.