Àpapọ̀ ẹgbẹ́ àwọn tí ó ń pèsè èédú jàkè-jádò orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti parí ètò láti se ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn ní ẹka ìpèsè èédú, nípa ipa pàtàkì tí ìdágbósí ń kó fún àlàáfíà àti ìdàgbásókè àwùjọ. Èyí tí yóò wáyé pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn nínú ẹka ìjọba.
Ẹgbẹ́ náà fi ọ̀rọ̀ léde fún àwọn akọ̀ròyìn ní ìlú Abuja, nígbà tí ó ń sàlàyé pé ètò náà yóò jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ mọ ìpalára tí Igi gígé ń fà àti ànfààní tí ó wà níbi Igi gbíngbìn ní àwùjọ wa.
Alága àpapọ̀ ẹgbẹ́ náà, Babatunde Edu sọ wípé igi gígé ń kópa nínú àyípadà ojú ọjọ́ èyí tí ó ń kó ìpalára bá oun ọ̀gbìn. Ó wá rọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ láti tẹ̀lé òfin àti àlàkalẹ̀ ìjọba lórí pàtàkì ìdágbósí àti Igi gbíngbìn.