Gómìnà Dave Umahi ti gba àwọn adarí ẹgbẹ́ òsèlú APC nímọ̀ràn láti pín ipò adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin ẹlẹ́ẹ̀kẹẹ̀wá sí ibi tí ó yẹ fún ìsọ̀kan àti ìfìdímúlẹ̀ ìjọba tiwa-n-tiwa.
Ó mú ìmọ̀ràn náà wá nígbà tí ó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé bòńkẹ́lẹ́ pẹ̀lú Ààrẹ Muhammadu Buhari ní ilé iṣẹ́ ààrẹ ní ọjọ́ Ìsẹ́gun, ní ìlú Abuja.
Gẹ́gẹ́ bí ó se sọ, pínpín ipò adarí káàkiri Ẹkùn Òsèlú yóò sàfihàn dọ́gba-n-dọ́gba àti ìsàfirinlẹ̀ ètò ìjọba. Ó wá lo ànfààní náà láti kí Ààrẹ Buhari fún àseyọrí ìdìbò gbogbogbòò ọdún 2023, léyìí tí Sẹ́nétọ̀ Bọla Tinubu jáwé olúborí.