Take a fresh look at your lifestyle.
Election

Àwọn Akọ̀ròyìn Ọmọ Orílẹ̀ Èdè France Méjì Rí Ẹ̀wọ̀n He Látàrí Ìbanilórúkọjẹ́

0 85

Àwọn akọ̀ròyìn méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọbíbí Orílẹ̀ Èdè France ni wọ́n ti dá ẹ̀wọ̀n ọdún kan fún àti sísan owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (Euro) nígbà tí wọ́n jẹ̀bi ẹ̀sùn ìgbìyànjú láti ba Adarí Orílẹ̀ Èdè Morocco lórúkọ jẹ́ àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà ní ọdún 2015.

 

Agbejọ́rò àwọn akọ̀ròyìn náà rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ilé-ẹjọ́ wípé àwọn oníbàárà òun kò jẹ̀bi sùgbọ́n àsìṣe wáyé fún ìdúnàá-dúrà láti gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lójúná àti má jẹ̀ kí ìwé ìbanilórúkọjẹ́ náà jáde.

 

Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Ilé-ẹjọ́ dáwọn lẹ́bi nítorí pé àwọn akọ̀ròyìn náà ni wọ́n bèèrè fún owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀, kìí se ìjọba Orílẹ̀ Èdè Morocco. Ilé-ẹjọ́ wá fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé, àdápa irọ́ ni ìwé tí àwọn akọ̀ròyìn náà kọ, Ó sì jùwọ́n sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan gbáko pẹ̀lú sísan owó gbà má bínú fún Ìjọba Morocco.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.