Take a fresh look at your lifestyle.

A Ò Sègbè Lẹ́yìn Ẹgbẹ́ Òsèlú Tàbí Olùdíje Kankan- Àjọ Elétò Ìdìbò

0 112

Kọmísánnà Àpapọ̀ Ètò Ìdìbò, Ajagunfẹ̀yìntì Modibo Alkali fi hàn gbangba wípé Àjọ Elétò Ìdìbò kò sègbè lẹ́yìn ẹgbẹ́ òsèlú tàbí olùdíje kankan jákè-jádo Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà.

 

Alkali fi ọ̀rọ̀ náà léde nígbà tí ó ń sèpàdé pẹ̀lú àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ àti àwọn asojú ẹgbẹ́ òsèlú ní ìpínlẹ̀ Sokoto.

 

Ó fi àrídájú hàn pé àjọ náà yóò se àtúnṣe àwọn àseètó tí ó wáyé nínú ìdìbò gbogbogbòò ti ọjọ́ kẹẹ̀dọ́ọ́gbọ̀n osù kejì léyìí tí yóò sì ríi dájú pé ẹ̀rọ BVAS yẹ àwọn olùdìbò wò síwájú kí wọn tó dìbò.

 

Ó sàlàyé síwájú pé òun wá láti se ìrànlọ́wọ́ fún alákòsóo ètò ìdìbò ti Ìpínlẹ̀ sokoto, Hajiya Hauwa Kangiwa àtipé òun yóò pinwọ́ mọ̀kàrúrù àti ìwà jàgídíjàgan nínú ètò ìdìbò. Alkali wá fi àrídájú ìgbáradì àjọ náà léde fún ètò ìdìbò Gómìnà àti Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin tí yóò wáyé ní ọjọ́ kejìdílógún osù kẹta.

Leave A Reply

Your email address will not be published.