Take a fresh look at your lifestyle.

Wọ́n Yan Ògbẹ́ni Jesse Otegbayo Sí Ipò Ọgá Àgbà UCH Ní Ẹlẹ́ẹ̀kejì

0 290

 

Ìjọba àpapọ̀ ti yan ọgá àgbà Ilé Ìwòsàn University College Hospital(UCH) Ìbàdàn, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, sí ipò fún ọdún mẹ́rin ẹlẹ́ẹ̀kejì.

 

Ààrẹ Muhammadu Buhari fi ọwọ́ sí ìyànsípò Ọ̀gbẹ́ni Otegbayo gẹ́gẹ́ bí CMD ilé ìwòsàn náà ni osu kínní ọdún 2019.
Mínísítà fún ètò ìlera, Ọ̀gbẹ́ni Osagie Ehanire ló kéde rẹ̀ ní ọjọ́ Ajé ní ilyu Ìbàdàn, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

 

Ọ̀gbẹ́ni Ehanire fi leta ìyànsípò tuntun rẹ lée lọ́wọ́ nínú gbọ̀ngàn iyàrá kan nínú ilé ìwòsàn ti Ìbàdàn náà.

 

Ọ̀gbẹ́ni Otegbayo, tó gbàṣẹ lọ́wọ́ Ọ̀gbẹ́ni
Temitope Alonge, ló jẹ́ ọmọ bíbí Ọtan-Ile ní ìjọba ìbílẹ̀ Obòkun ní ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, Ìpínlẹ̀ Osun.
Ó kàwé yege jáde ní ifáfitì ti Ẹ̀kọ́ Ìkọ́ni ní ètò ìmọ̀ Ìṣègùn ti Ìbàdàn ní ọdún 1989.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.