Take a fresh look at your lifestyle.

Osimhen Jẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Tó Dára Jùlọ Ní Àgbáyé -Troost-Ekong

0 236

 

Igbákejì Adarí agbábọ́ọ̀lù Super Eagles, Troost-Ekong ti sọ pé Victor Osimhen ni agbábọ́ọ̀lù tó ń gbá bọ́ọ̀lù sínú àwọ̀n tó dára jùlọ ní àgbáyé látàrí àrà ọ̀tọ̀ tó ń fi gbá bọ́ọ̀lù rẹ̀ tó wuni fún ikọ̀ Napoli ni Sáà yìí

Ọ̀dọ́mọdé ọmọ ọdún mẹ́rìn lé lógún náà ti fakọ yo ní Sáà yìí ní ìgbàtí ó gbá bọ́ọ̀lù mọ́kàndínlógún sínú àwọ̀n nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ méjìlelógún.

O gbá agbábọ́ọ̀lù tó se dáradára jùlọ ní oṣù kínní, bọ́ọ̀lù àrà tó gbá sí àwọ̀n bí ti Ògbóǹtarìgì agbábọ́ọ̀lù Pele tún jẹ́ kí wọ́n kéde rẹ̀ pé òun ló tún gba olóríre agbábọ́ọ̀lù tó dáńgájíá jùlọ níbi ká gbá bọ́ọ̀lù tó dára sí àwọ̀n ti Ìdíje Serie A, oṣù kan náà.

Agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ Lille tẹ́lẹ̀ rí náà, jẹ́ kí ikọ̀ rẹ̀ wà lókè téńté Tábìlì, tí wọ́n sì ń lé iwájú pẹ̀lú ayò méjìdínlógún tí wọ́n fi tayọ ikọ̀ tí ó wà ní ipò kejì lórí Tábìlì. Àrídájú ti wà pé ó seése kí ikọ̀ rẹ̀ ṣe ipò kínní kí wọ́n sì gba ife ẹ̀yẹ ti Liigi ti Italo tí yóò jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ lẹ́yìn ọgbọ̀n ọdún.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.