Take a fresh look at your lifestyle.
Election

Mínísítà Eré Ìdárayá Ṣọ̀fọ̀ Akọ́ni-mọ̀ọ́gbá Super Falcons, Mabo

0 146

 

Mínísítà fún Eré Ìdárayá, Sunday Dare nígbà tí ó ń se ìdàrò Akọ́ni-mọ̀ọ́gbá ẹni ire tó lọ, ọ̀gbẹ́ni Ismaila Mabo, sọ pé Erin ńlá nínú eré bọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti lọ ní igbó.

 

Ọ̀gbẹ́ni Mabo kú ní ọjọ́ Ajé ní Ìlú Jos, Ìpínlẹ̀ Plateau ní ọjọ́ orí Ọgọrin ọdún.

 

Mínísítà sọ pé, “Pa Ismaila Mabo gbé ìgbé-ayé tó dara tó ní àwòkọ́ṣe rere. Ibi tó dára ló wà fún un tí wọ́n bá ń kọ ìtàn bọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè yíi.”
Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilé ìwé, Ó sojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, lẹ́yìn tí ó fẹ̀yìntì, Ó tún di Akọ́ni-mọ̀ọ́gbá fún Super Falcons tí o sì gbé wọn dé èbúté ògo ní ilẹ Adúláwọ̀ àti káàkiri gbogbo àgbáyé.
Kí Ọlọ́run tẹ ṣí afẹ́fẹ́ rere, kò tu àwọn ẹbí rẹ̀ nínú. “
Mínísítà sọ bẹ́ẹ̀

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.