Take a fresh look at your lifestyle.

Mẹ́tàléláàdọ̀ta Ènìyàn Tó Wà Ní Ilé Ìwòsan Látàrí Ìjàmbá Ọkọ̀ Reluwé Àti Ọkọ̀ Bọ́ọ̀sì Orí Ilẹ̀ Jáde Lọ Ilé Wọn Láyọ̀

0 332

 

Ọ̀kàn lé lógún ènìyàn ló ti dara pọ̀ mọ́ àwọn tó lọ ilé wọn láti ilé ìwòsàn látàrí ìjàmbá ọkọ̀ àti ọkọ̀ ojú-irin tó wáyé ní Sógúnlè, ìpínlẹ̀ Èkó nígbà tí àwọn ènìyàn – òṣìṣẹ́ ìjọba ń lọ sí ibi iṣẹ́ wọn. Gbogbo àwọn tó ti lọ ilé wọn ní àlàáfíà ti jẹ́ Mẹ́tàléláàdọ̀ta lápapò.

 

Àwọn mẹ́tàlélógójì tó farapa sì ń gba ìtọjú ní ilé ìwòsàn ti ẹkọ́ni ti LASUTH, Ìkẹjà, General Hospital Odan-Lagos àti General Hospital, Gbàgádà.

Bákannáà, àgùnbánirọ̀ kan tó wà lára àwọn mẹ́fà tó gbẹ̀mí mì ni wọ́n ti sin òkú rẹ.

Ìròyìn ró pé, Awakọ̀ ọkọ̀ náà ti ń gba ìtöjú ní ilé ìwòsàn ní òpin ọ̀sẹ̀ ni Òyìngbò ní kété tó kúrò ní àtìmọ́lé gẹ́gẹ́ bí Kọmísọ́nà ètò ìlera, Akin Abayomi, se sọ.

 

Ọ̀gbéni Àbáyọ̀mí fi kún pé àwọn tó gbẹ̀mí mì kò tíì kọjá mẹ́fà.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button