Take a fresh look at your lifestyle.
Election

BBTitans: Blaqboi Di Olórí Ilé Tuntun

0 99

 

Méjì nínú àwọn alábágbélépọ̀ ti Big Brother Titans, Ipeleng àti Blaqboi ti di olórí ilé tuntun alájọsepọ̀ ti eré
ìgbéwò òdodo tó ń lọ lọ́wọ́.

Bí eré náà se ń parí lọ, ìdíje olórí ilé náà ń le síi, gbogbo olùkópa ló ń múra láti yege nítorí kò sí àsìkò púpọ̀ tó bẹ̀ mọ́.

Lẹ́yìn ìdíje ti èní, Blaqboi di olórí ilé tuntun, ó yan Blue Aiva láti gbádùn ipò olórí (HoH) pẹ̀lú rẹ̀.

Ní àṣálẹ́ tó kọjá, Ipeleng tó ti ní anfààní ní ipele àsekágbá ni wọ́n sọ fún kí o yan enìkan tó ti di dandan fún ti yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ ní àsekágbá, ó sì yan Ebubu sí ìyàlẹ́nu àwọn ènìyàn nítorí pé wọn rò pé yóò yan Miracle àti Blaqbloi.

Wọn gbàgbọ́ pé ẹni tó dára ló yàn.
Ìdíje náà yóò tẹnu bọpo ní ọjọ́ Kejìlá, Oṣù Kẹrin, ọdún 2023.

Alábágbélépọ̀ méjìlá ni ó kù báyìí. Àwọn ni: Ebubu, Tsatsii, Nana, Thabana, Justin, Yvonne, Blue Aiva, Kanaga Jnr., Blaqboi, ati Ipeleng, Khosi, ati Miracle OP.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.