Ní ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́rin sí mẹ́ta tí ìdìbò Gómìnà àti Ilé Aṣòfin ní Ìpínlẹ̀ Kwara, àrin gbùngbùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò wáyé, Akọ̀we Alábójútó tuntun míràn ni wọ́n ti yàn fún àjọ INEC ti Ìpínlẹ̀ Kwara.
Mallam Shehu Maiyanga ni orúkọ rẹ̀ ń jẹ́, ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Kogi ni ń se.
Akọ̀wé Alábójútó tuntun náà yóò gbasẹ́ lọ́wọ́ ọ̀gbẹ́ni Julius Yagba tó ń fẹ̀yìntì lẹ́nu Iṣẹ́.
Ògbẹ́ni Maiyanga ni ọ̀gá àgbà ti àjọ General Administration and Procurement (GAP) ní Ìpínlẹ̀ Nasarawa.
Maiyanga dara pọ̀ mọ́ àjọ náà ní ọdún ọdún 1988, Ó ṣiṣẹ́ ní ófíìsì INEC ní ìpínlẹ̀ Benue àti Kogi, ó tún jẹ́ òṣìṣẹ́ ètò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Kwara ní ìdìbò ti ọdún 2011.
Ẹni tó ń lọ àti ẹni ń wọlé ti jọ tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn Ìjáde àti ìwọlé lẹ́ye ò sokà.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply