Ẹgbẹrun àwọn Oníṣègùn Òyìnbó ló bẹ̀rẹ̀ ìyansẹ́lódí látàrí owó oṣù tí kò ṣe dédé.
Ẹgbẹ́ àwọn Oníṣègùn Òyìnbó sọ pé owó sísan fún àwọn Oníṣègùn kékèké ko gbọdọ kéré sí 14.09 pound fun wákàtí kan, wọ́n ní tó ba tí kéré sí èyí àbùkù ni.
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ ìlera ti pe ẹgbẹ́ awọn Oníṣègùn Òyìnbó fún àtúnṣe àti iyànjú lórí ọ̀rọ̀ náà.