Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Muhammed Buhari ti ki Ààrẹ Xi Jinping ku Orire fún atuyan rẹ sí ipò Ààrẹ ọlọ́dún márún-ún fún ìgbà kẹta.
Ààrẹ nígbàgbọ́ pé la bẹ akoso Aarẹ Xi, ìbáṣepọ̀ láàrin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti orílẹ̀-èdè China tí ó ti bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1971 yóò túbọ̀ gbilẹ̀ sí.
Ààrẹ ni gbagbọ Pé ọjọ́ iwájú ìbáṣepọ̀ orílẹ̀-èdè Méjèjì yóò mu ìtẹ́síwájú ba ètò ọ̀rọ̀ òṣèlú, epo ròbì, ìṣúná owó, gáàsì, ètò ọ̀gbìn àti Ìdàgbàsókè ìlú.
Ààrẹ Buhari ṣadura fún ìjọba àti àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè China fún Àlàáfíà, Ìgbega, irorun labẹ àkoso Ààrẹ Xi.